Mó wó réré ayé, mo wo ṣàkun gbogbo n ǹ kan. Nínú àwòjinlẹ̀ mi, mo wá ri p’ọ́rọ̀ ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fì s’íbìkan ju ‘bìkan lọ.

Lóọọ́tọ́, Olúùlú n’Ìbádàn ti jẹ̀ lát’ìgbà ìjọba ìwọ-oòrùn Nàìjíríà l’ásìkò t’Áwólọ́wọ̀, Akíntọ́lá àt’àwọn Ológun fi ṣè’jọba. Látàrí i pé’bàdàn j’Ólúùlú, gbogbo àǹfààní tó tọ́ s’Ólúùlú ló má ń wà níbẹ̀.
Kó tó di pé n ǹ kán bẹ̀rẹ̀ sí d’íbàjẹ́, ipò Olúùlú t’Íbàdàn dìmú ló ṣokùnfà gbogbo àwọn ohun ìgbáyé-gbádùn bíi iná mànàmáná, omi ẹ̀rọ, ilé iṣẹ́ ẹ asọ̀rọ̀ mágbèsì àti móhùn-máwòrán, ilé ìṣẹ́ ẹ̀rọ tẹlifóònù, ọ̀dà ojú ọ̀nà tí wọn pa láró tó ń yọ̀ kùlùlù bí ẹní dami síwájú àt’áwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga bí Yunifásítì, ilẹ́ ẹ̀kọ́ ìmọ́-ẹ̀rọ, ìlé ẹ̀kọ̀-àwọn ọlùkọ́ tó sodo s’ẹ́kùn Ìbàdàn, ilẹ́ ẹ̀kọ́ àgbẹ̀, ilé ẹ̀kọ̀ ìlera ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ba ṣe r’áwọn ilẹ́ ẹ̀kọ́ tó yanranntí nílùú Ìbàdàn, bẹ́ẹ̀ náà la r’áwọn ilẹ́ iṣẹ́ ńlá ńla tó jẹ́ t’Ìjọba ati t’aládàáni. Àwọn n ǹ kan wọnyí ò p’òjù fún ‘bi ta pè l’Ólúùlú láti ní.
Lẹ́yìn àwọn n ǹ kan tí mó là kalẹ̀ pó yẹ k’Ólúùlú ó ni, ẹ jẹ́ á padà s’óríi ọ̀rò ọ ìmúnilẹ́rú. Ohun tí mo fẹ́ kọ́kọ́ sọ ni pé, lóòótọ́ l’oókì Ìbádàn sò pé “Ìbádàn Ajòrosùn, ọmọ a f’ìgbín bọ karahun f’ọ́rí mu. Ìbàdàn má já má já bo ṣe k’árá ‘wájú l’ẹ́rú. Ìbàdàn ń m’ẹ́rú. Gbogbo wa wá d’abẹ́rú ń m’ẹ́rú l’ójú ogun. Ìbàdàn ìlú Àjàyí, ìlú Òjó, ìlú Ìbíkúnlé, Ìlú Ògúnmọ́lá, olódògbo kẹ̀ri kẹ̀ri l’ójú ogun”, ìmúnilẹ́rú àwọn Òkèògùn, Ìbàràpá, Ọ̀yọ́ àt’Ògbómọ̀ṣọ́ kò t’ọwọ́ ‘bàdàn wá.
L’ édè kúkúrú, Ìbádàn ó kó wa l’ẹ́rú àwa làá ń dá kún ìmúnilẹ́rú tó ń bá wa fín’ra lát’ọdún yí wá. Àbí kí lẹ ní mo wí? Kí lẹ́ ní mo sọ.
Owe tó bá wa mu l’òwe Yóòbá tó ní: b’íkú ll’lé ò pa ni, t’òde ò lè rí ni pa.
Òwe míì tó tún b’ọ́rọ̀ tó wà ń lẹ̀ yí ni: “b’ógiri ò la’nu aláǹgbá ò lè r’ọ́nà wọ bẹ̀”.
Ṣe Yóòbá náà ló tún bùṣe gàdà ti wọ́n tún wí pé: “kòkòrò tí ń j’ẹ̀fọ́, ìdí ẹ̀fọ́ ló wà”.
Tótó ṣe ní òwe, ẹ̀yin àgbàgbà!
Ká tó lè r’ọ́nà lọ t’ọ́mọ ọ̀kan nínú àwọn ẹkùn tí wọn ń f’ọwọ́jánú pé ‘bàdàn ń r’áwọn jẹ ó tó lẹ̀ di Gómìnà n’Ípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, ó d’ìgbà t’ọ́kọ̀ọkan nínú àwọn ẹkùn bá w’ójúùtú s’áwọn kùdìẹ kudiẹ tó ń bá wọn fín’ra tí wọn wá na’wọ́jà àjọṣepọ̀ tó gúnmọ́ sí’ra wọ́n láti dìbò ẹlẹ́yọkan tó jẹ́ jáde láti’ nú u ìfohùn-ṣọ̀kan.
Ìbàdàn ti d’Erin lákátabú tí Kìnìún ẹyọkan ò gbọdọ̀ d’ojúkọ àfi tó bá wọ káà ‘lẹ̀ lọ láìtọ́jọ́. Ṣ’ùgbọ́n àjọ́ṣepọ̀ àwọn ọba ẹranko l’ọ̀nà àbáyọ láti b’oríi lákátabú l’Áginjù.
Bí n bá ní n s’àsọkúnná ọ̀rọ̀ f’ápẹẹrẹ gẹ́gẹ́bí ọmọ Òkèògùn nípa kúdìẹ̀ kudiẹ tí ń bá wa jà, ilẹ̀ ó rẹ t’orí ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwé e kọ́bọ̀. Ṣùgbọ́n, kí n ge pé pè pé bí awo bàbà ìṣọnà, àtòsílẹ̀ àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ tó ń bá wa fín’ra tí ò jẹ́ á r’ọ́nà lọ ló wà lẹ́yọkọọkan l’éní-tere èjì-tere ẹ̀kẹta-làjẹ-ǹ-jẹ-tán ní sàlẹ̀ yí:
Kùdìẹ̀ kudie àkọ́kọ́ ni tó f’ọwọ́ ago wa sẹ́yìn ni gbígba ipò o igbàkejì tàb’álága ẹgbẹ́ òṣèlú ní gbogbo gbà.
Ipò o ìgbákejì ó burú rara. Ohun náà l’áǹfàní tó pọ̀ láti mú wá. Ṣùgbọ́n, kó wa d’oyè gbogbo ‘gbà táb’óyè ‘dílé ba ṣe ǹ ríi ní gbogbo’ gbà yẹ kó mú ‘fura dání.
Ó ba d’ébi pé ipò igbákejì i Gómìnà àt’Alága ẹ̀gbẹ́ òṣèlú kò sí bòmíì mọ́, àf’Òkèògùn. N’ígbà tó ṣẹ̀ ń pọ jù àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàpèjúwe ipò ìgbákejì i Gómìnà pé “igbákígbá n’igbá kejì” ni. Àwọn míì ó tì ẹ̀ l’èdè èèbó bí wọn bá fẹ́ ṣàpèjúwe, wọn á ni “spare tyre”.
Kùdìẹ̀ kudie kejì ni Ọọ̀rọ̀ ẹ̀sìn èyí ta fi ń d’íjà lẹ̀ láàrin ara wa tí ò jẹ́ Mùsùlùmí ó m’ọmọ ìyá rẹ̀ láàrin àwọn Ońgbàgbọ́ tàbí t’Òńgbàgbọ́ ó bìkítà láti f’àwọn Mùsùlùmí ọmọ ìyá a rẹ̀ mọ́’ra láti ṣ’àṣepọ̀ èyí tó lè ṣ’okùnfà àṣeyọrí.
Yóòbá ló sọ p’ẹ́sìn ó f’àjà. Ṣùgbọ́n, ba a bá w’ohun tó ń ṣẹ lẹ̀ l’áyé t’ékèé d’áyé t’ááṣà d’Ápòmù yí, a ó ri p’ẹ́sìn to kó ‘dá mẹ́sàń nínú ìdámẹ́wàá gbogbo ìjà tí ń lọ l’ágbàáyé. Nítorí ẹ̀sìn baba ó gbọ́ t’ọmò mọ́, iyèkan ń y’àdá sí’ra wọ̀n. Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti sọnù lọ́jọ̀ àìpé làtàrí ìjà ẹ̀sìn.
Ká tó r’ ọ́nà àbáyọ, a gbọdọ̀ gbà pé ẹmí l’Ọlọ́run, gbogbo àwọn tó ń sìn-ín gbọdọ̀ sìn-ín l’ẹ́mìí àti l’ótìítọ́. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa gbọdọ̀ gbà pé ẹ̀sìn ìyá ọ̀ gb’ọmọ là, kálukú ló ń ṣe ti ẹ.
Ohun tí mò ń gbìyànjú láti ní pé òfin f’àyè gb’ońkálukú láti ṣ’ẹ̀sìn tó wù ú. Gbogbo wa la sì gbọdọ̀ k’ófin Ọlọ́run àt’ọfin èèyàn já ba bá fẹ́ gbé l’àlàáfíà láàrin ara wa.
Ba bá fẹ́ k’àwùjọ wa ó ma tòrò bí omi àf’òwúrọ pọn ní gbogbo ‘gbà, a gbọdọ̀ màa f’ìfẹ́ tòótọ́ b’ára wa gbé toríi ìfẹ́ l’Ọlọ́run, ìfẹ́ lànílò, Ìfẹ̀sowápọ̀, ìfẹ́ dára àti pé làkójá-òfin.
N ǹ kan míì tí mó tún lè sọ nípa rẹ̀ ni ba se ń ṣ’òṣèlú. Lọ́dọ̀ wa, òṣèlú ẹgbẹ́ là ń ṣe lát’ọjọ́ Aláyé ti d’áyé. Ì bá dára bó bá jẹ́ p’óṣèlú u ẹgbẹ́ ní gbogbo Nàìjíríà ń ṣe èyí tíi bá mú ‘dágbásókè bá gbogbo wa. Ṣùgbọ́n, òṣèlú u ọmọ èni kìí ṣè’dí bẹ̀bẹ̀rẹ̀ ká fi s’ídìí ọmọ ẹlòmíì l’áwọn míi ń ṣe tí wọn fi ń rẹ̀ wa jẹ́.
Bóyá kí n la ọ̀rọ̀ l’ójú kó lè yé wa, òṣèlú ẹgbẹ́ tá à ń ṣe l’ágbègbè wa ti d’òṣèlú u afọ̀jú. Ẹgbẹ́ ṣáá ní gbogbo ‘gbà tí ò mú n ǹ kan kan wá bá wa lát’ìgbà àwọn baba wa. Ba bá ń ṣe n ǹ kan bákannáà ní gbogbo ‘gbà tó jé’rú èsì kannàá là ń rí ní gbogbo’ gbà, sa nílò o babaláwo láti sọ fún wa pé kò s’ọ́nà níbẹ̀ ni?
Èyí tó wá burú jù n’ìjà àjàkú-Akátá àt’ìjà àjátúká ni t’Àgbáàrín ta ma ń jà lágbo òṣèlú. Òṣèlú tó jẹ́ p’éré làá f’ọmọ-ayò ṣe l’àwòn yókù fi ń ṣ’òṣèlú làwa má a ń mú le kan kan kan dé bi wí pé à ń p’ara wa torí ẹ̀.
Ba à bá wa’wọ́ èyí bọ’ lẹ̀ láàrin wa, ká ṣ’òṣèlú tí ó mú’ dàgbásókè àt’ìlòsíwájú b’ágbègbè wa, ibi kọ̀ t’éèbó f’ẹnu ọkọ̀ sọ’lẹ̀ náà la á ma b’ára wa toríi ba bá s’Abẹ̀bẹ̀ s’ókè n’ígbà ‘gba, ibi pẹlẹbẹ ní ó ma fi lé’ lẹ̀.
Ọ̀rọ míì tó tún fa kùdìé kudiẹ l’ọ́wọ́ l’ọ̀rọ̀ ọ onílùú-jìlú. Kò s’óhun tó burú k’éèyàn ó f’ẹ́ràn ìlú ẹ̀. Ọlọ́run fẹ́ ká fẹ́ràn ìlú u abínibí wa àt’ìlú táà ń gbé. Ìserere ońkálukú u wa sopọ̀ mó dada ta bá ṣe s’áwọn ìlú méjéèjì yí.
Ṣùgbọ́n, bó ti wù ká f’ẹ́ràn ìlú wa tó, ó yẹ́ ká ma j’ọwọ́ lẹ̀ b’ọ́rọ̀ bá di t’agbègbè wa. Agbègbè gbọdọ̀ múmú l’áyà wa jú ‘lú wa lọ ba bá gbé méjéèjì sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọ́n.
F’ápẹẹrẹ, k’íjòba ó fẹ́ fún wa ní n ǹ kan l’ágbẹgbè wa ká má lè sọ pàtó ìlú tó yẹ ká gbe sí àfi kó d’ìjà rannto láàrin wa eléyìí tó ti ṣ’àkóba fún wa látẹ̀yìn wá.
Ba à bá m’ọ́rọ̀ yí kúrò láàrin wa, ká ṣètò o pín’re làá’re èyí t’éèbó ń pé ní “formula” láti ma pín n ǹ kan tó bá ń wá sọ́dọ̀ wa, a ò ní lè ṣ’àṣeyọrí bó bá jẹ́ pé t’ìjà la ó ma fi ṣe.
Lákòótán ọ̀rọ̀, gbogbo ẹkùn ló ní kùdìẹ kudiẹ ti ẹ̀, t’Òkèògùn ní mò sọ kalẹ̀ yí, bí n bá ní n sò t’Ìbàràpá tí wọ́n j’ọ́mọ ìyá wa, ìlẹ̀ á kún fàya. Bẹ́ẹ̀ ni t’Ọyọ́, bẹ́ẹ̀ ni t’Ògbómọṣọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni t’Ìbàdàn toríi pé Ìbàdàn jù ‘bàdán lọ l’ágbọn òṣèlú bó bá di tipò o Gómìnà.
Nítorí náà, koko ọ̀rọ̀ mi ni pé, enì kan kìí jẹ́ k’ílẹ̀ ó fẹ̀. Owe yìí ló yẹ ká mú lò ká fi ṣ’àtúnṣe b’ága Gómìnà ó fi ma yí ká a gbogbo ẹkùn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lá ì dá b’ìkan sí.
Ẹ ṣe é, mo dúpẹ́.
Òǹkọ̀wé:
Òlùṣọ́-Àgùntàn Favour A. Adéwọyin, Àkọ̀wé e Ẹgbẹ́ Àjọṣepọ̀ Fún Ìtẹsiwájú Gbogbo Wa.