Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kan ti wà rí tó j’ọ́kan lára àwọn ìpínlẹ̀ ta yọ kúrò nínú u àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ni ìwọ òòrun orílẹ̀-èdè e Naijiria n’ígbà kan rí. Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ alákọ̀ọ́kọ́ yí ló wà papọ̀ pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Ọṣun.

L’ ọ́jọ́ kẹtàdínlógbọ̀n, oṣù kẹjọ, odún un 1991 ní ìjọba Ológun, lábẹ́ ìṣàkóso Ọ̀gágun Ibrahim Badamosi Babangida, yọ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ titun kúrò l’ára ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ̀ ọ t’àtijọ́ èyí tó tún fa ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun jáde.
Ṣùgbọ́n, l’ọ́dun un 1979 sí 1983, lásìkò òṣèlú ẹlẹ́ẹ̀kejì, Olóyè Bọ́lá Ìgè, ọmọ bíbí Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà lát’Ẹ̀sà-Òkè, tó ti bọ́dìí sí ‘pínlẹ̀ Ọṣun báyìí ló jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àtijọ́ tí Olóyè Sunday. M Afòlábí, ọmọ bíbí ìlú Ìré Alálùbọ́sà ní ‘pínlẹ̀ Ọṣun, n’igbákejì i Gómìnà.
L’ àsìkò tí mò ń s’ọ̀rọ̀ rẹ̀ yí, kò s’Òṣèlú u ẹ̀sìn tàb’ónílùú-jìlú tó ti gogò láàrin wa l’óde òní. Gómìnà Bọ́lá Ìgè, Ọ̀ṣun ló ti wá, onígbàgbọ́ ọmọ lẹ́yìn in Jẹ́sù ni. Igbákejìi Gómìnà, Ọṣun ló ti wá, onígbàgbọ́ ọmọ lẹ́yìn-in Jẹ́sù l’òun náà. Kò sí jà, kò síta rárá, òṣèlú Náìjíríà dára n’ígbà àtijọ́.
Ẹgbẹ́ ẹ “Ìmọ́lẹ̀” (Unity Party of Nigeria) lábẹ́ ìṣàkóso Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, ọkọ Hannah Dídéolú, ọmọ Ẹfúnyẹlá, Òṣèlú baba Ìkẹ́nnẹ́ àt’ẹgbẹ́ “onílé” (National Party of Nigeria) tí Olóyè Meridith Àdìsá Akinloyè l’àwọn ẹgbẹ́ tó f’èsẹ̀-rinlẹ̀ ní ‘pínlé Ọ̀yọ́.
Olóyè Awólọ́wọ̀ du’pò ààrẹ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò wọle. Alhaji Shehu Shagari l’okùn-un ààrẹ Orile-ede Naijiria já mọ́ lọ́wọ́.
Kẹ̀kẹ̀ kẹ̀rẹ̀, ìṣèjọba ń lọ ní mẹ̀lọ mẹ̀lọ, gbogbo ètò ń tò, ètò ìjọba ń lọ dada. Ṣùgbọ́n, Gómìnà Bọ́lá Ìgè s’ọ̀rọ̀ kan jáde tó tako Ìbàdàn èyí tó sọ wọ́n jí kúrò nínú oorun òṣèlú. Gbólóhùn tí Gómìnà Bọ́lá Ìgè sọ nipé “kò s’ọ̀mọ ‘bàdàn kan tó kájú ẹ̀ láti ṣe Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Gbólóhùn yí là ń bá yí títí tó e d’òní ní ‘pínlẹ̀ Ọ̀yọ́ n’ìgbà t’Íbàdàn ó ṣe tán láti f’oyè Gómìnà lẹ̀ mọ́ f’ẹ́nìkan kan.
Ọ̀mọwé Victor Ọmọlolú Olúnlọ́yọ̀ọ́ n’Ìbàdàn fà kalẹ̀ pó k’ójú òsùnwọ̀n l’ọ́dún náà, a sì dìbò fun un, ó sì wọlé. Ṣùgbọ́n, orí ní mú ni dé’pò, orí náà làá lò láti fi ṣe’pò ba bá dé’ pò ọhún. Ọmọlolú Olúnlọ́yọ̀ọ́ ò pẹ́ nípò, kò j’oṣù mẹ́ta sí mẹ́rin lọ t’àwọn atiláawí ológun tún gbàjọba, tí wọn sì tún f’ìjọba kàn-ń-pá àwọn ológun lọ̀’lẹ̀.
Ìjọba Ológun gbàjọba lọ́wọ́ àwọn alágbádá tí ń ṣè’jọba tiwa-n-tiwa, Ọ̀gágun Mohammadu Buhari ló j’olórí ìjọba àwọn Ológun t’Ọ́gágun Túndé Ìdíàgbọn, tó le bí àpáàrà, sì jẹ́ igbákejì rẹ̀.
Ìjọba Ológun tún ṣè’jọba sàà lọ fún’gbà díẹ̀ kí wọ́n ó tún tó gbe f’áwọn alágbádá tí mo s’ọrọ̀ rẹ̀ ṣíwájú èyí tó sọ Olóyè Bọ́lá Ìgè, ọkọ Onídàájọ́ Atinúkẹ́ Ìgè (ọmọ Olọ́kọ́) di Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ odún t’Ólógun fi ṣè’jọba.
Ọdún un 1999 la tún bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò òṣèlú míì ta wà ninú rẹ̀ báyìí. A ó ṣàkíyèsí pé lát’igbà yí lọ ló ti di pé k’ibò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ó má y’ẹsẹ̀ kúrò n’Íbàdàn. Nínú àwọn Gómìnà ta ti ń ní ní ‘pìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, ọpọ’ gbà ló jẹ́ p’ọ́mọ bíbí i Ìjọba ‘bílẹ̀ mẹjì p’éré ló sì ti ń jẹ Gómínà. Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá (Ìbádàn North) àt’ìjọba Ìbílẹ̀ Gúsù u Ìbàdàn (Ìbádàn South). Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọkan ló ń wá láti bòmíì n’Íbàdàn gẹ́gẹ́bí ìgbà t’ólóyè Kọ́lápọ Ìṣọlá jẹ́ láti
Ó fihàn pèètè peete pé, yàtọ f’Ókèògùn, Ọyọ́ àt’Ìbàràpá tí ò tíì ṣe Gómìnà rí èyí t’Ógbòómọṣọ́ ṣèèsì ṣe é lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo, àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Ìbàdàn míì bíi Omí Àdìó, Àkánrán, Akínyẹlẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, kò tíì l’Àǹfàní láti dépò o Gómìnà.
Bó ti wá rí bàyìí, ohun tó kàn tó sì jẹ́ ‘mọ̀ràn tó dára ni pé ká gb’ara wa n’ímọràn kí jọba ó máa yí lát’ẹkùn kan sékejì. Òkèògùn l’áwọn ọmọ tó ká’jú òṣùwọ̀n tí wọn lé dipò o Gómìnà mú. Ọyọ́ l’áwọn ọmọ tó ká’jú ẹ̀ tí wọn lé dipò o Gómìnà mú. Ìbàràpa l’áwọn ọmọ tó ká’jú ẹ̀ tí wọn lé dipò o Gómìnà mú. Ògbómọ̀ṣọ́ l’áwọn ọmọ tó ká’jú ẹ̀ tí wọn lé dipò o Gómìnà mú. Àwọn àgbègbè Ìbàdàn tí ò tíì jẹ Gómìnà rí náà l’áwọn ọmọ tó ká’jú ẹ̀ tí wọn lé dipò o Gómìnà mú.
Ìdí àbájọ nìyí ta ṣe kó’ra wa jọ́ n’ílé l’óko àti lẹ́yìn odi, ta dá “Ẹgbẹ́ Àjọṣepọ̀ Fún Ìtẹ̀síwájú u gbogbo wa”.
Ṣé Yóòbá wọ́n ní: màkàn màkàn l’oyè é kán, oyè tó kan ará Awó ń bọ̀ wá kan ará Ẹdẹ. Tótó ṣebí òwe ẹ̀yin ará. Àfojúsùn wa nínú Ẹgbẹ́ Àjọṣepọ̀ Fún Ìtẹsiwájú Gbogbo Wa ní kí ipò Gómìnà ó ma yí káàkiri gbogbo agbègbè bí wọn ṣe ń ṣe é l’áwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní ìwọ òòrun un Gúsù u Nàìjíríà.
A sì ti gb’àwọn Ìgbẹ́sẹ̀ kọ̀ọkan láti lè mú’ran wa wá wá símùúṣẹ, a ó sì túnbọ̀ tẹ̀síwájú nínú u ìgbẹ́sẹ̀ ta á ma gbé, toríi pé b’íná ò bẹ́ tán l’áṣọ, Yóòbá l’ẹ́jẹ̀ kìí tán lẹ́ẹ̀kánná. Tótó se bí òwe ẹ̀yìn àgbà tí ń jẹ̀sẹ́bì.
Lákòótán l’áàárọ̀ yí, mó gbàdúrà k’Ọ́lọ́run dé ìgbìnyànjú u wa l’Ádé láṣẹ Èdùmàrè. N’ígbà tó bá dára tán, ká má f’ẹnìkan ṣàwátì láàrin wa.
Mó lérò pe’bí dára láti fẹ́nu ọkọ̀ àrọ̀sọ tó jẹ mọ́ ìtàn ọṣèlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yí sọ ‘lẹ̀.
Ó tún d’ ìgbà míì l’ọ́lá Áláwùrà.
Orúkọ mi ni: Olùṣọ́-Àgùntàn Favour Adéwálé Adéwọyin.
Akọ̀wé gbo gbo gbò fún Ẹgbẹ́ Àjọṣepọ̀ Fún Ìtẹsiwájú Gbogbo Wa.