N’ílé iṣẹ́ Asọ̀rọ̀ mágbèsì kan t’éèbó ń pè ní Rédíò t’ọ́ọ́kọ rẹ̀ ń jẹ́ “Honour 103.5 FM” l’ádùúgbò o Bódìjà l’ólúùlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ṣe Ìbàdàn la wà lánà t’Ólóòtú ètò o Gbàgede-ọ̀rọ̀ t’ọ́ọ́kọ rẹ̀ ń jẹ́ Abídèmí Àkàndé Ọ̀rọ̀-àgbà ń f’ọ̀rọ̀ j’omitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wa l’óríi Ẹgbẹ́ Àjọṣepọ̀ Fún Ìtẹsiwájú Gbogbo Wa t’áfojúsùn rẹ̀ pè fún pé k’ágbára ìjòba àt’ìṣèjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ó ma yípo láàrin àwọn ẹ̀kùn márùń tó wà n’Ípìńlẹ̀ káàrọ̀-o-ò-jíire.

Ba à bà gbàgbé, ẹ̀kùn márùń ló wà n’Ípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ṣè ‘pínlẹ̀ Aṣájú. A ní ẹkùn Ìbàdàn tó n’íjọba ìpínlẹ̀ mọ́kànlá nínú u ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. A ní ẹkùn Òkèògùn tó n’íjọba ìpínlẹ̀ mẹ́wàá nínú u ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, Ọ̀yọ́ n’íjọba ìpínlẹ̀ mẹ́rin, Ìbàràpá n’íjọba ìpínlẹ̀ mẹ́ta, Ògbómọ̀ṣọ́ n’íjọba ìpínlẹ̀ márùn nínú u ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.
Lati bí ọ̀dún méjìlélógójì tí Bọ́lá Ìgè tó jẹ́ ‘jẹ̀ṣà ti gbé’jọba lé l’Ọ́mololú Olúnlọ́yọ̀ọ́ tó j’ójúlówó ọmọ bíbí Ìbàdàn lọ́wọ́ l’ódun 1983 l’ọmọ Ìbàdàn ti ń ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ẹ̀ẹ̀kan péré l’ọmò Ọ̀gbómọ̀ṣọ́, Olóyè Àlàó-Akálà, ṣ’èèṣì jẹ Gómìnà f’ọ́dún mẹ́rin. Ó fihàn gbangba p’ọdúnméjìdínlógójì n’Ìbàdàn ti ń ṣàkóso ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ba bá tún ní ká d’àálẹ̀ ká tun ṣà, a ó ri pé, yàtọ s’ẹ́ẹ̀kan t’Ólóyè Kọ́lápọ̀ Ìṣọ̀lá tó wá lát’ìjọba Ìbílẹ̀ Akínyẹlé, lát’Àríwá pẹ̀lú u Gúúsù Ìbàdàn ni Gómìnà ti ń sábà ti máa ń wá. Èyí fi hàn pé lát’Ìbàdàn lọ́ l’àwọn ‘jọba ìbílẹ̀ tí ń nágà wó ìjòkó o Gómìnà l’ Ágodi tó e d’Ókèègùn, Ìbàràpá, Ọ̀yọ́ àt’Ògnọ́mọ̀ṣọ́.
Ṣùgbọ́n, bó ti wá pẹ́ tó t’Íbàdàn ti ń ṣe Gómìnà, ọ̀pọ̀ nínú Ìbàdàn ní ó rántí ìtàn p’ákòókò kan wà t’Íjẹ̀ṣà ń ṣe wọ́n bí ẹrú n’ílùú baba wọn. Ìbàdàn ń ṣe bí ẹni ti g’òkè-odò k’áfárá ó tó já. Wọ́n gbàgbé òwe Yóòbá tó l’ẹ́nìkan kìí jẹ k’ílẹ̀ ó fẹ̀.
N’ílé Àsọ̀rọ̀ mágbèsì i “Honour 103.5FM” lánàá, lẹ́yìn ìfọ̀rọ-jomitoro-ọ̀rọ̀, Olóòtú ṣ’ójú-òpó ẹ̀rọ́-gàásímilétí sílẹ̀ láti f’áwọn èèyàn l’áǹfàní láti pè wọlé. Àwọn èèyàn bíi mẹ́ta sí mẹ́rin tó pé wọ́lé ní wọ́n dúró lóríi pé ‘bàdàn náà ń ó ma lo’pò o Gómìnà lọ́ bó ti wù kó rí. Òwe tí wọn pa ní pé: “ba bá j’abẹ̀bẹ̀ s’óke n’ígbà a ‘gba, ibi pẹlẹbẹ náà ní ó ma fi lé’ lẹ̀”.
Ọ̀kan mí bàjẹ́ n’ígbà tí mo gb’ésì yí lát’ọ̀dọ̀ àwọn olùpè, ẹ̀rù sì bà mí gidigidi f’ọ́mọ ẹ̀nìyàn lát’àríi wípé a ò hùwà bí Ọlọ́run. Ọlọ́run tí ń r’òjò fún gbogbo wa láì fi t’ìlú, t’ẹ̀sìn, t’óṣèlú àt’àwọn n ǹ kan míì ṣe. Kìí ṣ’ọ̀rọ̀ Gómìnà nìkan làá ń sò, ní gbogbo ọ̀nà la fí ń rẹ́ ‘ra wa jẹ ta kọ̀ láti fi t’Ọ́lọ́run wàwò-kọ́ṣe pé ká fẹ́ràn òmònìkejì wa bí ara wa.
Yóòbá tó sọ pé ká f’iná jó ‘ra wà bó ṣe rí ká tó fi j’énìyàn ègbẹ́ wa. Yóòbá ná ló tún béèrè pé kí l’Ọbọ́ fi ṣ’orí t’Ínàkí ò ṣe? Ohun tó dáa fún Kẹ́hìndé yẹ́ kó dáa fún Táyé papàá.
Lákòótán ọ̀rọ mi, òwe tó tún wá s’ọ́kàn mi tó jẹ́ m’óhun tí mó ń sò ni òwe t’Ólùkọ́ mi kan máa ń pa tó lọ́ báyìí pé: a fá orí Igún, a yẹ́ t’Àkàlàmàgbò l’ẹ́sẹ̀, a wá dá t’Àtíòro sí. Ṣé t’Ìkóríra ni àb’ábẹ ni ò mú”?
N’íparí ọ̀rọ mi, ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń f’ámòójútó, kò sì ṣe é wò n’íran. N ǹ kan ó gbọdọ̀ ma lọ́ báyìí ba bá fẹ́ ‘lọsíwájú u gbogbo ẹkùn tó wà n’ ípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́. A gbodọ ṣ’àtúnṣe kí n ǹ kan ó tó bọ́ órí.
Ẹ ṣe é, mo dúpẹ́ dúpẹ́.
Àròkọ látọwọ́ ọ:
Olùṣọ̀-Àgùntàn Favour A. Adéwọyin, Akọ̀wé e gbo gbo gbò fún Ẹgbẹ́ Àjọṣepọ̀ Fún Ìtẹsiwájú Gbogbo Wa.